Native Bible

1 Chronicles 15:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Aaroni àti àwọn ọmọ Lefi tí Dafidi péjọ papọ̀.

1 Chronicles 15:4 in English

1 Chronicles 15:4 · Berean Standard Bible

Then he gathered together the descendants of Aaron and the Levites:

Context

2Nígbà náà Dafidi wí pé, kò sí ẹnìkan àyàfi àwọn ọmọ Lefi ni ó lè gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, nítorí Olúwa yàn wọ́n láti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú rẹ̀ títí láé. 3Dafidi kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ ní Jerusalẹmu láti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa wá sí ibi tí ó ti pèsè sílẹ̀ fún un. 4Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Aaroni àti àwọn ọmọ Lefi tí Dafidi péjọ papọ̀. 5Ọgọ́fà nínú àwọn ọmọ Kohati; Urieli olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀. 6Igba ó lé ogún nínú àwọn ọmọ Merari; Asaiah olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.