1 Kronika 14:8
1 Chronicles 14:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí àwọn ará Filistini gbọ́ pé a ti fi àmì òróró yàn Dafidi ní ọba lórí gbogbo Israẹli, wọ́n sì lọ sókè pẹ̀lú ipá láti wá a rí, ṣùgbọ́n Dafidi gbọ́ nípa rẹ̀ ó sì jáde lọ láti pàdé wọn.
1 Chronicles 14:8 in English
1 Chronicles 14:8 · Berean Standard Bible
When the Philistines heard that David had been anointed king over all Israel, they all went in search of him; but David learned of this and went out to face them.
Context
6Noga, Nefegi, Jafia, 7Eliṣama, Beeliada, àti Elifeleti. 8Nígbà tí àwọn ará Filistini gbọ́ pé a ti fi àmì òróró yàn Dafidi ní ọba lórí gbogbo Israẹli, wọ́n sì lọ sókè pẹ̀lú ipá láti wá a rí, ṣùgbọ́n Dafidi gbọ́ nípa rẹ̀ ó sì jáde lọ láti pàdé wọn. 9Nísinsin yìí àwọn ará Filistini ti wá láti gbógun ti àfonífojì Refaimu; 10Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run wí pé, “Kí èmi kí ó gòkè tọ àwọn ará Filistini lọ bí? Ìwọ ó ha fi wọ́n lé mi lọ́wọ́?”
Olúwa sì wí fún un pé, “Gòkè lọ èmi ó sì fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.