Sefaniah 3:7
Zephaniah 3:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi wí fún ìlú náà wí pé, ‘Nítòótọ́, ìwọ yóò bẹ̀rù mi, ìwọ yóò sì gba ìtọ́ni!’ Bẹ́ẹ̀ ni, a kì yóò ké ibùgbé rẹ̀ kúrò bí ó ti wù kí ń jẹ wọ́n ní yà tó. Ṣùgbọ́n síbẹ̀ wọ́n sì tún ní ìtara láti ṣe ìbàjẹ́.
Zephaniah 3:7 in English
Zephaniah 3:7 · Berean Standard Bible
I said, ‘Surely you will fear Me and accept correction.’ Then her dwelling place would not be cut off despite all for which I punished her. But they rose early to corrupt all their deeds.
Context
5Olúwa ni àárín rẹ̀ jẹ́ olódodo;
kì yóò ṣe ohun tí kò tọ̀nà.
Àràárọ̀ ni ó máa ń mú ìdájọ́ rẹ̀ wá sí ìmọ́lẹ̀,
kì í sì kùnà ní gbogbo ọjọ́ tuntun,
síbẹ̀ àwọn aláìṣòótọ́ kò mọ ìtìjú. 6“Èmi ti ké àwọn orílẹ̀-èdè kúrò,
ilé gíga wọn sì ti bàjẹ́.
Mo ti fi ìgboro wọn sílẹ̀ ní òfo
tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnìkankan kò kọjá níbẹ̀.
Ìlú wọn parun tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí
ẹnìkan tí yóò ṣẹ́kù,
kò sì ní sí ẹnìkan rárá. 7Èmi wí fún ìlú náà wí pé,
‘Nítòótọ́, ìwọ yóò bẹ̀rù mi,
ìwọ yóò sì gba ìtọ́ni!’
Bẹ́ẹ̀ ni, a kì yóò ké ibùgbé rẹ̀ kúrò
bí ó ti wù kí ń jẹ wọ́n ní yà tó.
Ṣùgbọ́n síbẹ̀ wọ́n sì tún ní ìtara
láti ṣe ìbàjẹ́. 8Nítorí náà ẹ dúró dè mí,” ni Olúwa wí,
“títí di ọjọ́ náà tí èmi yóò fi jẹ́rìí sí yin.
Nítorí ìpinnu mi ni láti kó orílẹ̀-èdè jọ
kí èmi kí ó lè kó ilẹ̀ ọba jọ
àti láti da ìbínú mi jáde sórí wọn,
àní gbogbo ìbínú gbígbóná mi.
Nítorí gbogbo ayé
ni a ó fi iná owú mi jẹ run. 9“Nígbà náà ni èmi yóò yí èdè àwọn ènìyàn padà sí èdè mímọ́,
nítorí kí gbogbo wọn bá a lè máa pe orúkọ Olúwa,
láti fi ọkàn kan sìn ín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.