Sekariah 7:12
Zechariah 7:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n sé ọkàn wọn bí òkúta líle, kí wọn má ba à gbọ́ òfin, àti ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti fi ẹ̀mí rẹ̀ rán nípa ọwọ́ àwọn wòlíì ìṣáájú wá. Ìbínú ńlá sì dé láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
Zechariah 7:12 in English
Zechariah 7:12 · Berean Standard Bible
They made their hearts like flint and would not listen to the law or to the words that the LORD of Hosts had sent by His Spirit through the earlier prophets. Therefore great anger came from the LORD of Hosts.
Context
10Má sì ṣe ni opó lára tàbí aláìní baba, àlejò, tàbí tálákà; kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe gbèrò ibi ní ọkàn sí arákùnrin rẹ̀.’ 11“Ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀ láti gbọ́, wọ́n sì gún èjìká, wọ́n sì pa ẹ̀yìn dà, wọ́n di etí wọn, kí wọn má ba à gbọ́. 12Wọ́n sé ọkàn wọn bí òkúta líle, kí wọn má ba à gbọ́ òfin, àti ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti fi ẹ̀mí rẹ̀ rán nípa ọwọ́ àwọn wòlíì ìṣáájú wá. Ìbínú ńlá sì dé láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun. 13“ ‘Ó sì ṣe, gẹ́gẹ́ bí ó ti kígbe, tí wọn kò sì fẹ́ gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kígbe, tí èmi kò sì fẹ́ gbọ́,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 14‘Mo sì fi ìjì tú wọn ká sí gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọn kò mọ̀. Ilẹ̀ náà sì dahoro lẹ́yìn wọn, tí ẹnikẹ́ni kò là á kọjá tàbí kí ó padà bọ̀, wọ́n sì sọ ilẹ̀ ààyò náà dahoro.’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.