Sekariah 7:10
Zechariah 7:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Má sì ṣe ni opó lára tàbí aláìní baba, àlejò, tàbí tálákà; kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe gbèrò ibi ní ọkàn sí arákùnrin rẹ̀.’
Zechariah 7:10 in English
Zechariah 7:10 · Berean Standard Bible
Do not oppress the widow or the fatherless, the foreigner or the poor. And do not plot evil in your hearts against one another.’
Context
8Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Sekariah wá, wí pé, 9“Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, ‘Ṣe ìdájọ́ òtítọ́, kí ẹ sì ṣe àánú àti ìyọ́nú olúkúlùkù sí arákùnrin rẹ̀. 10Má sì ṣe ni opó lára tàbí aláìní baba, àlejò, tàbí tálákà; kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe gbèrò ibi ní ọkàn sí arákùnrin rẹ̀.’ 11“Ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀ láti gbọ́, wọ́n sì gún èjìká, wọ́n sì pa ẹ̀yìn dà, wọ́n di etí wọn, kí wọn má ba à gbọ́. 12Wọ́n sé ọkàn wọn bí òkúta líle, kí wọn má ba à gbọ́ òfin, àti ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti fi ẹ̀mí rẹ̀ rán nípa ọwọ́ àwọn wòlíì ìṣáájú wá. Ìbínú ńlá sì dé láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.