Sekariah 4:11
Zechariah 4:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo sì béèrè, mo sì sọ fún un pé, “Kí ni àwọn igi olifi méjì wọ̀nyí jásí, tí ó wà ní apá ọ̀tún fìtílà àti ní apá òsì rẹ̀?”
Zechariah 4:11 in English
Zechariah 4:11 · Berean Standard Bible
Then I asked the angel, “What are the two olive trees on the right and left of the lampstand?”
Context
9“Ọwọ́ Serubbabeli ni a ti ṣe ìpìlẹ̀ ilé yìí, ọwọ́ rẹ̀ ni yóò sì parí rẹ̀; ìwọ yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi sí i yín. 10“Ṣùgbọ́n ta ni ha kẹ́gàn ọjọ́ ohun kékeré? Nítorí wọn ó yọ̀ nígbà ti wọ́n bá rí okùn ìwọ̀n nì lọ́wọ́ Serubbabeli.
“(Àwọn méje wọ̀nyí ni àwọn ojú Olúwa, tí ó ń sáré síyìn-ín sọ́hùn-ún ní gbogbo ayé.)” 11Mo sì béèrè, mo sì sọ fún un pé, “Kí ni àwọn igi olifi méjì wọ̀nyí jásí, tí ó wà ní apá ọ̀tún fìtílà àti ní apá òsì rẹ̀?” 12Mo sì tún dáhùn, mo sì sọ fún un pé, “Kí ni àwọn ẹ̀ka méjì igi olifi wọ̀nyí jásí, tí ń tú òróró wúrà jáde nínú ara wọn láti ẹnu ọ̀pá oníhò wúrà méjì.” 13Ó sì dáhùn, ó wí fún mi pé, “Ìwọ kò mọ ohun tí àwọn wọ̀nyí jásí?”
Mo sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, olúwa à mi.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.