Native Bible

Zechariah 4:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mo sì tún dáhùn, mo sì sọ fún un pé, “Kí ni àwọn ẹ̀ka méjì igi olifi wọ̀nyí jásí, tí ń tú òróró wúrà jáde nínú ara wọn láti ẹnu ọ̀pá oníhò wúrà méjì.”

Zechariah 4:12 in English

Zechariah 4:12 · Berean Standard Bible

And I questioned him further, “What are the two olive branches beside the two gold pipes from which the golden oil * pours?”

Context

10“Ṣùgbọ́n ta ni ha kẹ́gàn ọjọ́ ohun kékeré? Nítorí wọn ó yọ̀ nígbà ti wọ́n bá rí okùn ìwọ̀n nì lọ́wọ́ Serubbabeli. “(Àwọn méje wọ̀nyí ni àwọn ojú Olúwa, tí ó ń sáré síyìn-ín sọ́hùn-ún ní gbogbo ayé.)” 11Mo sì béèrè, mo sì sọ fún un pé, “Kí ni àwọn igi olifi méjì wọ̀nyí jásí, tí ó wà ní apá ọ̀tún fìtílà àti ní apá òsì rẹ̀?” 12Mo sì tún dáhùn, mo sì sọ fún un pé, “Kí ni àwọn ẹ̀ka méjì igi olifi wọ̀nyí jásí, tí ń tú òróró wúrà jáde nínú ara wọn láti ẹnu ọ̀pá oníhò wúrà méjì.” 13Ó sì dáhùn, ó wí fún mi pé, “Ìwọ kò mọ ohun tí àwọn wọ̀nyí jásí?” Mo sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, olúwa à mi.” 14Ó sì wí pé, “Àwọn méjì wọ̀nyí ni àwọn tí a fi òróró yàn, tí ó dúró ti Olúwa gbogbo ayé.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.