Native Bible

Zechariah 10:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Efraimu yóò sì ṣe bí alágbára, ọkàn wọn yóò sì yọ̀ bi ẹni pé nípa ọtí wáìnì: àní àwọn ọmọ wọn yóò rí í, wọn o sì yọ̀, inú wọn ó sì dùn nínú Olúwa.

Zechariah 10:7 in English

Zechariah 10:7 · Berean Standard Bible

Ephraim will be like a mighty man, and their hearts will be glad as with wine. Their children will see it and be joyful; their hearts will rejoice in the LORD.

Context

5Gbogbo wọn yóò sì dàbí ọkùnrin alágbára ni ogun tí ń tẹ àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀ ní ìgboro, wọn ó sì jagun, nítorí Olúwa wà pẹ̀lú wọn, wọn ó sì dààmú àwọn tí ń gun ẹṣin. 6“Èmi o sì mú ilé Juda ní agbára, èmi o sì gba ilé Josẹfu là, èmi ó sì tún mú wọn padà nítorí mo tí ṣàánú fún wọn, ó sì dàbí ẹni pé èmi kò ì tì í ta wọ́n nù; nítorí èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn, èmi o sì gbọ́ tiwọn 7Efraimu yóò sì ṣe bí alágbára, ọkàn wọn yóò sì yọ̀ bi ẹni pé nípa ọtí wáìnì: àní àwọn ọmọ wọn yóò rí í, wọn o sì yọ̀, inú wọn ó sì dùn nínú Olúwa. 8Èmi ó kọ sí wọn, èmi ó sì ṣà wọ́n jọ; nítorí èmi tí rà wọ́n padà; wọn ó sì pọ̀ sí i gẹ́gẹ́ bí wọ́n tí ń pọ̀ sí í rí. 9Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo tú wọn káàkiri orílẹ̀-èdè: síbẹ̀ wọn ó sì rántí mi ni ilẹ̀ jíjìn; wọn ó sì gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, wọn ó sì tún padà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.