Sekariah 10:5
Zechariah 10:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo wọn yóò sì dàbí ọkùnrin alágbára ni ogun tí ń tẹ àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀ ní ìgboro, wọn ó sì jagun, nítorí Olúwa wà pẹ̀lú wọn, wọn ó sì dààmú àwọn tí ń gun ẹṣin.
Zechariah 10:5 in English
Zechariah 10:5 · Berean Standard Bible
They will be like mighty men in battle, trampling the enemy in the mire of the streets. They will fight because the LORD is with them, and they will put the horsemen to shame.
Context
3“Ìbínú mi ru sí àwọn darandaran,
èmi o sì jẹ àwọn olórí ní yà
nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti bẹ agbo rẹ̀,
ilé Juda wò,
yóò sì fi wọn ṣe ẹṣin rẹ̀ dáradára ní ogun. 4Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni òkúta igun ilé ti jáde wá,
láti ọ̀dọ̀ rẹ ni èèkàn àgọ́ tí wá,
láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrún ogun tí wá,
láti ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn akóniṣiṣẹ́ gbogbo tí wá. 5Gbogbo wọn yóò sì dàbí ọkùnrin
alágbára ni ogun tí ń tẹ àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀ ní ìgboro, wọn ó sì jagun,
nítorí Olúwa wà pẹ̀lú wọn,
wọn ó sì dààmú àwọn tí ń gun ẹṣin. 6“Èmi o sì mú ilé Juda ní agbára,
èmi o sì gba ilé Josẹfu là,
èmi ó sì tún mú wọn padà
nítorí mo tí ṣàánú fún wọn,
ó sì dàbí ẹni pé èmi kò ì tì í ta wọ́n nù;
nítorí èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn,
èmi o sì gbọ́ tiwọn 7Efraimu yóò sì ṣe bí alágbára,
ọkàn wọn yóò sì yọ̀ bi ẹni pé nípa ọtí wáìnì:
àní àwọn ọmọ wọn yóò rí í,
wọn o sì yọ̀, inú wọn ó sì dùn nínú Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.