Sekariah 10:11
Zechariah 10:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọn yóò sì la Òkun wàhálà já, yóò sì bori rírú omi nínú Òkun, gbogbo ibú odò ni yóò sì gbẹ, a ó sì rẹ ìgbéraga Asiria sílẹ̀, ọ̀pá aládé Ejibiti yóò sí lọ kúrò.
Zechariah 10:11 in English
Zechariah 10:11 · Berean Standard Bible
They will pass through the sea of distress and strike the waves of the sea; all the depths of the Nile will dry up. The pride of Assyria will be brought down, and the scepter of Egypt will depart.
Context
9Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo tú wọn káàkiri orílẹ̀-èdè:
síbẹ̀ wọn ó sì rántí mi ni ilẹ̀ jíjìn;
wọn ó sì gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn,
wọn ó sì tún padà. 10Èmi ó sì tún mú wọn padà kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti pẹ̀lú,
èmi ó sì ṣà wọn jọ kúrò ni ilẹ̀ Asiria.
Èmi ó sì mú wọn wá sí ilẹ̀ Gileadi àti Lebanoni;
a kì yóò sì rí ààyè fún wọn bí ó ti yẹ. 11Wọn yóò sì la Òkun wàhálà já,
yóò sì bori rírú omi nínú Òkun,
gbogbo ibú odò ni yóò sì gbẹ,
a ó sì rẹ ìgbéraga Asiria sílẹ̀,
ọ̀pá aládé Ejibiti yóò sí lọ kúrò. 12Èmi ó sì mú wọn ní agbára nínú Olúwa;
wọn ó sì rìn sókè rìn sódò ni orúkọ rẹ̀,”
ni Olúwa wí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.