Sekariah 1:16
Zechariah 1:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí: ‘Mo padà tọ Jerusalẹmu wá pẹ̀lú àánú; ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, a ó kọ́ ilé mi sínú rẹ̀, a o sí ta okùn ìwọ̀n kan jáde sórí Jerusalẹmu.’
Zechariah 1:16 in English
Zechariah 1:16 · Berean Standard Bible
Therefore this is what the LORD says: ‘I will return to Jerusalem with mercy, and there My house will be rebuilt, declares the LORD of Hosts, and a measuring line will be stretched out over Jerusalem.’
Context
14Angẹli ti ń bá mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Ìwọ kígbe wí pé, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Èmi ń fi ìjowú ńlá jowú fún Jerusalẹmu àti fún Sioni. 15Èmi sì bínú púpọ̀púpọ̀ si àwọn orílẹ̀-èdè tí ó rò wí pé òun ní ààbò. Nítorí nígbà tí mo bínú díẹ̀, wọ́n ran ìparun lọ́wọ́ láti tẹ̀síwájú.’ 16“Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí: ‘Mo padà tọ Jerusalẹmu wá pẹ̀lú àánú; ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, a ó kọ́ ilé mi sínú rẹ̀, a o sí ta okùn ìwọ̀n kan jáde sórí Jerusalẹmu.’ 17“Máa ké síbẹ̀ pé, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘A o máa fi ìre kún ìlú ńlá mi síbẹ̀; Olúwa yóò sì máa tu Sioni nínú síbẹ̀, yóò sì yan Jerusalẹmu síbẹ̀.’ ” 18Mo si gbé ojú sókè, mo sì rí, sì kíyèsi i, ìwo mẹ́rin.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.