Sekariah 1:15
Zechariah 1:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi sì bínú púpọ̀púpọ̀ si àwọn orílẹ̀-èdè tí ó rò wí pé òun ní ààbò. Nítorí nígbà tí mo bínú díẹ̀, wọ́n ran ìparun lọ́wọ́ láti tẹ̀síwájú.’
Zechariah 1:15 in English
Zechariah 1:15 · Berean Standard Bible
but I am fiercely angry with the nations that are at ease. For I was a little angry, but they have added to the calamity.*’
Context
13Olúwa sì fi ọ̀rọ̀ rere àti ọ̀rọ̀ ìtùnú dá angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ lóhùn. 14Angẹli ti ń bá mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Ìwọ kígbe wí pé, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Èmi ń fi ìjowú ńlá jowú fún Jerusalẹmu àti fún Sioni. 15Èmi sì bínú púpọ̀púpọ̀ si àwọn orílẹ̀-èdè tí ó rò wí pé òun ní ààbò. Nítorí nígbà tí mo bínú díẹ̀, wọ́n ran ìparun lọ́wọ́ láti tẹ̀síwájú.’ 16“Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí: ‘Mo padà tọ Jerusalẹmu wá pẹ̀lú àánú; ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, a ó kọ́ ilé mi sínú rẹ̀, a o sí ta okùn ìwọ̀n kan jáde sórí Jerusalẹmu.’ 17“Máa ké síbẹ̀ pé, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘A o máa fi ìre kún ìlú ńlá mi síbẹ̀; Olúwa yóò sì máa tu Sioni nínú síbẹ̀, yóò sì yan Jerusalẹmu síbẹ̀.’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.