Orin Solomoni 6:3
Song of Songs 6:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi ni ti olùfẹ́ mi, olùfẹ́ mi sì ni tèmi, Ó ń jẹ láàrín ìtànná lílì.
Song of Songs 6:3 in English
Song of Songs 6:3 · Berean Standard Bible
I belong to my beloved and he belongs to me; he pastures his flock among the lilies.
Context
1Níbo ni olùfẹ́ rẹ lọ,
ìwọ arẹwà jùlọ láàrín àwọn obìnrin?
Níbo ni olùfẹ́ rẹ yà sí,
kí a lè bá ọ wá a? 2Olùfẹ́ mi ti sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ọgbà rẹ̀,
sí ibi ibùsùn tùràrí,
láti máa jẹ nínú ọgbà
láti kó ìtànná lílì jọ. 3Èmi ni ti olùfẹ́ mi, olùfẹ́ mi sì ni tèmi,
Ó ń jẹ láàrín ìtànná lílì. 4Ìwọ lẹ́wà olùfẹ́ mi, bí i Tirsa,
ìwọ lẹ́wà bí i Jerusalẹmu,
ìwọ ògo bí ogun pẹ̀lú ọ̀págun. 5Yí ojú rẹ kúrò lára mi;
nítorí ojú rẹ borí mi.
Irun rẹ rí bí i ọ̀wọ́ ewúrẹ́
tí ó sọ̀kalẹ̀ wá láti Gileadi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.