Orin Solomoni 5:8
Song of Songs 5:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, mo bẹ̀ yín bí ẹ̀yin bá rí olùfẹ́ mi, kí ni ẹ̀yin yóò wí fún un? Ẹ wí fún un pé àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mi.
Song of Songs 5:8 in English
Song of Songs 5:8 · Berean Standard Bible
O daughters of Jerusalem, I adjure you, if you find my beloved, tell him I am sick with love.
Context
6Èmi ṣí ìlẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,
ṣùgbọ́n olùfẹ́ mi ti kúrò, ó ti lọ
ọkàn mi gbọgbẹ́ fún lílọ rẹ̀.
Mo wá a kiri ṣùgbọ́n, n kò rí i.
Mo pè é ṣùgbọ́n, kò dáhùn. 7Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ ìlú rí mi
bí wọ́n ti ṣe ń rìn yí ìlú ká.
Wọ́n nà mí, wọ́n sá mi lọ́gbẹ́;
wọ́n gba ìborùn mi lọ́wọ́ mi.
Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ odi! 8Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, mo bẹ̀ yín
bí ẹ̀yin bá rí olùfẹ́ mi,
kí ni ẹ̀yin yóò wí fún un?
Ẹ wí fún un pé àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mi. 9Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tókù lọ,
ìwọ arẹwà jùlọ láàrín àwọn obìnrin?
Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tókù lọ
tí ìwọ fi ń fi wá bú bẹ́ẹ̀? 10Olùfẹ́ mi ní ìtànṣán ó sì pọ́n
ó ní ọlá ju ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) lọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.