Orin Solomoni 5:2
Song of Songs 5:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
(1) Ẹ jẹ, ẹ̀yin ọ̀rẹ́, ẹ mu, àní ẹ mu àmuyó, ẹ̀yin olùfẹ́.
Song of Songs 5:2 in English
Song of Songs 5:2 · Berean Standard Bible
(1) Eat, O friends, and drink; drink freely, O beloved.
Context
1Mo ti dé inú ọgbà mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi;
mo ti kó òjìá pẹ̀lú òórùn dídùn mi jọ.
Mo ti jẹ afárá mi pẹ̀lú oyin mi;
mo ti mu ọtí wáìnì mi pẹ̀lú wàrà mi. 2(1) Ẹ jẹ, ẹ̀yin ọ̀rẹ́, ẹ mu,
àní ẹ mu àmuyó, ẹ̀yin olùfẹ́. 3(2) Mo ti sùn ṣùgbọ́n ọkàn mi jí.
Gbọ́! Olólùfẹ́ mi ń kan ìlẹ̀kùn.
“Ṣí i fún mi, arábìnrin mi, olùfẹ́ mi,
àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi,
orí mi kún fún omi ìrì,
irun mi kún fún òtútù òru.”
(3) Mo ti bọ́ aṣọ ìgúnwà mi
ṣé èmi gbọdọ̀ tún gbé e wọ̀?
Mo ti wẹ ẹsẹ̀ mi
ṣé èmi gbọdọ̀ tún tì í bọ eruku? 4Olùfẹ́ mi na ọwọ́ rẹ̀ láti inú ihò ìlẹ̀kùn
inú mi sì yọ́ sí i.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.