Native Bible

Romans 11:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nípa ti ìyìnrere, ọ̀tá ni wọ́n nítorí yín; bí ó sì ṣe ti ìyànfẹ́ ni, olùfẹ́ ni wọ́n nítorí ti àwọn baba.

Romans 11:28 in English

Romans 11:28 · Berean Standard Bible

Regarding the gospel, they are enemies on your account; but regarding election, they are loved on account of the patriarchs.

Context

26Bẹ́ẹ̀ ni a ó sì gba gbogbo Israẹli là, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Ní Sioni ni Olùgbàlà yóò ti jáde wá, yóò sì yìí àìwà-bí-Ọlọ́run kúrò lọ́dọ̀ Jakọbu. 27Èyí sì ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn. Nígbà tí èmi yóò mú ẹ̀ṣẹ̀ wọn kúrò.” 28Nípa ti ìyìnrere, ọ̀tá ni wọ́n nítorí yín; bí ó sì ṣe ti ìyànfẹ́ ni, olùfẹ́ ni wọ́n nítorí ti àwọn baba. 29Nítorí àìlábámọ̀ ni ẹ̀bùn àti ìpè Ọlọ́run. 30Nítorí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin kò ti gba Ọlọ́run gbọ́ rí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí tí ẹ̀yin rí àánú gbà nípa àìgbàgbọ́ wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.