Ìfihàn 7:14
Revelation 7:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo sì wí fún un pé, “Olúwa mi, ìwọ ni o lè mọ̀.” Ó sì wí fún mí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni o jáde láti inú ìpọ́njú ńlá, wọ́n sì fọ aṣọ wọ́n, wọ́n sì sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́-àgùntàn náà.
Revelation 7:14 in English
Revelation 7:14 · Berean Standard Bible
“Sir,” I answered, “you know.” So he replied, “These are the ones who have come out of the great tribulation; they have washed their robes and made them white in the blood of the Lamb.
Context
12Wí pe:
“Àmín!
Ìbùkún, àti ògo,
àti ọgbọ́n, àti ọpẹ́, àti ọlá,
àti agbára àti ipá fún Ọlọ́run wa láé àti láéláé!
Àmín!” 13Ọ̀kan nínú àwọn àgbà náà si dáhùn, ó bi mí pé, “Ta ni àwọn wọ̀nyí tí a wọ ni aṣọ funfun? Níbo ni wọn sì ti wá?” 14Mo sì wí fún un pé, “Olúwa mi, ìwọ ni o lè mọ̀.”
Ó sì wí fún mí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni o jáde láti inú ìpọ́njú ńlá, wọ́n sì fọ aṣọ wọ́n, wọ́n sì sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́-àgùntàn náà. 15Nítorí náà ni,
“wọn ṣe ń bẹ níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run,
tí wọn sì ń sìn ín, lọ́sàn àti lóru nínú tẹmpili rẹ̀;
ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́ náà yóò si síji bò wọn. 16Ebi kì yóò pa wọn mọ́,
bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ kì yóò gbẹ́ wọ́n mọ́;
bẹ́ẹ̀ ni oòrùn kì yóò pa wọn
tàbí oorukóoru kan.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.