Native Bible

Revelation 7:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọ̀kan nínú àwọn àgbà náà si dáhùn, ó bi mí pé, “Ta ni àwọn wọ̀nyí tí a wọ ni aṣọ funfun? Níbo ni wọn sì ti wá?”

Revelation 7:13 in English

Revelation 7:13 · Berean Standard Bible

Then one of the elders addressed me: “These in white robes,” he asked, “who are they, and where have they come from?”

Context

11Gbogbo àwọn angẹli sì dúró yí ìtẹ́ náà ká, àti yí àwọn àgbà àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà ká, wọn wólẹ̀ wọn si dojúbolẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà wọ́n sì sin Ọlọ́run. 12Wí pe: “Àmín! Ìbùkún, àti ògo, àti ọgbọ́n, àti ọpẹ́, àti ọlá, àti agbára àti ipá fún Ọlọ́run wa láé àti láéláé! Àmín!” 13Ọ̀kan nínú àwọn àgbà náà si dáhùn, ó bi mí pé, “Ta ni àwọn wọ̀nyí tí a wọ ni aṣọ funfun? Níbo ni wọn sì ti wá?” 14Mo sì wí fún un pé, “Olúwa mi, ìwọ ni o lè mọ̀.” Ó sì wí fún mí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni o jáde láti inú ìpọ́njú ńlá, wọ́n sì fọ aṣọ wọ́n, wọ́n sì sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́-àgùntàn náà. 15Nítorí náà ni, “wọn ṣe ń bẹ níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run, tí wọn sì ń sìn ín, lọ́sàn àti lóru nínú tẹmpili rẹ̀; ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́ náà yóò si síji bò wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.