Native Bible

Revelation 2:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi mọ iṣẹ́ rẹ, àti ìpọ́njú, àti àìní rẹ—ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ ni ọ́, èmi sì mọ ọ̀rọ̀-òdì tí àwọn tí ń wí pé, Júù ni àwọn tìkára wọn, tí wọn kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ Sinagọgu ti Satani.

Revelation 2:9 in English

Revelation 2:9 · Berean Standard Bible

I know your affliction and your poverty—though you are rich! And I am aware of the slander of those who falsely claim to be Jews, but are in fact a synagogue of Satan.

Context

7Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò fi èso igi ìyè nì fún jẹ, tí ń bẹ láàrín Paradise Ọlọ́run. 8“Àti sí angẹli ìjọ ní Smirna kọ̀wé. Nǹkan wọ̀nyí ni ẹni tí í ṣe ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn wí, ẹni tí ó ti kú, tí ó sì tún yè. 9Èmi mọ iṣẹ́ rẹ, àti ìpọ́njú, àti àìní rẹ—ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ ni ọ́, èmi sì mọ ọ̀rọ̀-òdì tí àwọn tí ń wí pé, Júù ni àwọn tìkára wọn, tí wọn kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ Sinagọgu ti Satani. 10Má ṣe bẹ̀rù ohunkóhun tí ìwọ ń bọ wá jìyà rẹ̀. Kíyèsi i, èṣù yóò gbé nínú yín jù sínú túbú, kí a lè dán yin wò; ẹ̀yin ó sì ní ìpọ́njú ní ọjọ́ mẹ́wàá, ìwọ ṣa ṣe olóòtítọ́ dé ojú ikú, èmi ó sì fi adé ìyè fún ọ. 11Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun kì yóò fi ara pa nínú ikú kejì.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.