Ìfihàn 2:11
Revelation 2:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun kì yóò fi ara pa nínú ikú kejì.
Revelation 2:11 in English
Revelation 2:11 · Berean Standard Bible
He who has an ear, let him hear what the Spirit says to the churches. The one who overcomes will not be harmed by the second death.
Context
9Èmi mọ iṣẹ́ rẹ, àti ìpọ́njú, àti àìní rẹ—ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ ni ọ́, èmi sì mọ ọ̀rọ̀-òdì tí àwọn tí ń wí pé, Júù ni àwọn tìkára wọn, tí wọn kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ Sinagọgu ti Satani. 10Má ṣe bẹ̀rù ohunkóhun tí ìwọ ń bọ wá jìyà rẹ̀. Kíyèsi i, èṣù yóò gbé nínú yín jù sínú túbú, kí a lè dán yin wò; ẹ̀yin ó sì ní ìpọ́njú ní ọjọ́ mẹ́wàá, ìwọ ṣa ṣe olóòtítọ́ dé ojú ikú, èmi ó sì fi adé ìyè fún ọ. 11Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun kì yóò fi ara pa nínú ikú kejì. 12“Àti sì angẹli ìjọ ni Pargamu kọ̀wé.
Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ó ní idà mímú olójú méjì. 13Èmí mọ̀ ibi tí ìwọ ń gbé, àní ibi tí ìtẹ́ Satani wà. Síbẹ̀ ìwọ di orúkọ mi mú ṣinṣin. Ìwọ kò sì sẹ́ ìgbàgbọ́ nínú mi, pàápàá jùlọ ni ọjọ́ Antipa ẹlẹ́rìí mi, olóòtítọ́ ènìyàn, ẹni tí wọn pa láàrín yín, níbi tí Satani ń gbé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.