Native Bible

Revelation 2:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Síbẹ̀ èyí ni mo rí wí sí ọ, pé, ìwọ ti fi ìfẹ́ ìṣáájú rẹ sílẹ̀.

Revelation 2:4 in English

Revelation 2:4 · Berean Standard Bible

But I have this against you: You have abandoned your first love.

Context

2Èmi mọ iṣẹ́ rẹ, àti làálàá rẹ, àti ìfaradà rẹ, àti bí ara rẹ kò ti gba àwọn ẹni búburú, àti bí ìwọ sì ti dán àwọn tí ń pe ara wọn ní aposteli, tí wọ́n kì í sì í ṣe bẹ́ẹ̀ wo, tí ìwọ sì rí pé èké ni wọ́n, 3tí ìwọ sì faradà ìyà, àti nítorí orúkọ mi tí ó sì rọ́jú, tí àárẹ̀ kò sì mú ọ. 4Síbẹ̀ èyí ni mo rí wí sí ọ, pé, ìwọ ti fi ìfẹ́ ìṣáájú rẹ sílẹ̀. 5Rántí ibi tí ìwọ ti gbé ṣubú! Ronúpìwàdà, kí ó sì ṣe iṣẹ́ ìṣáájú; bí kò sì ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó sì tọ̀ ọ́ wá, èmi ó sì ṣí ọ̀pá fìtílà rẹ̀ kúrò ní ipò rẹ̀, bí kò ṣe bí ìwọ bá ronúpìwàdà. 6Ṣùgbọ́n èyí ni ìwọ ní, pé ìwọ kórìíra ìṣe àwọn Nikolatani, èyí tí èmi pẹ̀lú sì kórìíra.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.