Native Bible

Revelation 2:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Rántí ibi tí ìwọ ti gbé ṣubú! Ronúpìwàdà, kí ó sì ṣe iṣẹ́ ìṣáájú; bí kò sì ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó sì tọ̀ ọ́ wá, èmi ó sì ṣí ọ̀pá fìtílà rẹ̀ kúrò ní ipò rẹ̀, bí kò ṣe bí ìwọ bá ronúpìwàdà.

Revelation 2:5 in English

Revelation 2:5 · Berean Standard Bible

Therefore, keep in mind how far you have fallen. Repent and perform the deeds you did at first. But if you do not repent, I will come to you and remove your lampstand from its place.

Context

3tí ìwọ sì faradà ìyà, àti nítorí orúkọ mi tí ó sì rọ́jú, tí àárẹ̀ kò sì mú ọ. 4Síbẹ̀ èyí ni mo rí wí sí ọ, pé, ìwọ ti fi ìfẹ́ ìṣáájú rẹ sílẹ̀. 5Rántí ibi tí ìwọ ti gbé ṣubú! Ronúpìwàdà, kí ó sì ṣe iṣẹ́ ìṣáájú; bí kò sì ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó sì tọ̀ ọ́ wá, èmi ó sì ṣí ọ̀pá fìtílà rẹ̀ kúrò ní ipò rẹ̀, bí kò ṣe bí ìwọ bá ronúpìwàdà. 6Ṣùgbọ́n èyí ni ìwọ ní, pé ìwọ kórìíra ìṣe àwọn Nikolatani, èyí tí èmi pẹ̀lú sì kórìíra. 7Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò fi èso igi ìyè nì fún jẹ, tí ń bẹ láàrín Paradise Ọlọ́run.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.