Ìfihàn 18:7
Revelation 18:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Níwọ́n bí o ti yin ara rẹ̀ lógo tó, tí ó sì hùwà wọ̀bìà, níwọ̀n bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ dá a lóró kí ẹ sì fún un ní ìbànújẹ́; nítorí tí ó wí ní ọkàn rẹ̀ pé, ‘Mo jókòó bí ọbabìnrin, èmi kì sì í ṣe opó, èmí kì yóò sì rí ìbànújẹ́ láé.’
Revelation 18:7 in English
Revelation 18:7 · Berean Standard Bible
As much as she has glorified herself and lived in luxury, give her the same measure of torment and grief. In her heart she says, ‘I sit as queen; I am not a widow and will never see grief.’
Context
5Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ga títí dé ọ̀run,
Ọlọ́run sì ti rántí àìṣedéédéé rẹ̀. 6San an fún un, àní bí òun tí san án fún ní,
kí ó sì ṣe e ni ìlọ́po méjì fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀,
nínú ago náà tí o ti kún, òun ni kí ẹ sì kún fún un ni méjì. 7Níwọ́n bí o ti yin ara rẹ̀ lógo tó,
tí ó sì hùwà wọ̀bìà,
níwọ̀n bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ dá a lóró kí ẹ sì fún un ní ìbànújẹ́;
nítorí tí ó wí ní ọkàn rẹ̀ pé,
‘Mo jókòó bí ọbabìnrin,
èmi kì sì í ṣe opó, èmí kì yóò sì rí ìbànújẹ́ láé.’ 8Nítorí náà, ní ọjọ́ kan ni ìyọnu rẹ̀ yóò dé,
ikú, àti ìbìnújẹ́, àti ìyàn;
a ó sì fi iná sun ún pátápátá:
nítorí pé alágbára ni Olúwa Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀. 9“Àti àwọn ọba ayé, tí ó ti ń bá a ṣe àgbèrè, tiwọn sì ń hùwà wọ̀bìà, yóò sì pohùnréré ẹkún lé e lórí, nígbà tí wọn bá wo èéfín ìjóná rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.