Ìfihàn 18:4
Revelation 18:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo sì gbọ́ ohùn mìíràn láti ọ̀run wá, wí pé: “ ‘Ẹ ti inú rẹ̀ jáde, ẹ̀yin ènìyàn mi,’ kí ẹ ma bá a ṣe alábápín nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ẹ ma bà á sì ṣe gbà nínú ìyọnu rẹ̀.
Revelation 18:4 in English
Revelation 18:4 · Berean Standard Bible
Then I heard another voice from heaven say: “Come out of her, My people,* so that you will not share in her sins or contract any of her plagues.
Context
2Ó sì kígbe ní ohùn rara, wí pé:
“Babeli ńlá ṣubú! Ó ṣubú!
Ó sì di ibùjókòó àwọn ẹ̀mí èṣù,
àti ihò fún ẹ̀mí àìmọ́ gbogbo,
àti ilé fún ẹyẹ àìmọ́ gbogbo,
ilé fún ẹranko ìríra àti àìmọ́ gbogbo. 3Nítorí nípa ọtí wáìnì ìrunú àgbèrè rẹ̀ ni
gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú.
Àwọn ọba ayé sì ti bá a ṣe àgbèrè,
àti àwọn oníṣòwò ayé sì di ọlọ́rọ̀ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọ̀bìà rẹ̀.” 4Mo sì gbọ́ ohùn mìíràn láti ọ̀run wá, wí pé:
“ ‘Ẹ ti inú rẹ̀ jáde, ẹ̀yin ènìyàn mi,’
kí ẹ ma bá a ṣe alábápín nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,
kí ẹ ma bà á sì ṣe gbà nínú ìyọnu rẹ̀. 5Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ga títí dé ọ̀run,
Ọlọ́run sì ti rántí àìṣedéédéé rẹ̀. 6San an fún un, àní bí òun tí san án fún ní,
kí ó sì ṣe e ni ìlọ́po méjì fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀,
nínú ago náà tí o ti kún, òun ni kí ẹ sì kún fún un ni méjì.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.