Ìfihàn 18:3
Revelation 18:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí nípa ọtí wáìnì ìrunú àgbèrè rẹ̀ ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú. Àwọn ọba ayé sì ti bá a ṣe àgbèrè, àti àwọn oníṣòwò ayé sì di ọlọ́rọ̀ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọ̀bìà rẹ̀.”
Revelation 18:3 in English
Revelation 18:3 · Berean Standard Bible
All the nations have drunk * the wine of the passion of her immorality. The kings of the earth were immoral with her, and the merchants of the earth have grown wealthy from the extravagance of her luxury.”
Context
1Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí mo sì rí angẹli mìíràn, ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá ti òun ti agbára ńlá; ilẹ̀ ayé sì ti ipa ògo rẹ̀ mọ́lẹ̀. 2Ó sì kígbe ní ohùn rara, wí pé:
“Babeli ńlá ṣubú! Ó ṣubú!
Ó sì di ibùjókòó àwọn ẹ̀mí èṣù,
àti ihò fún ẹ̀mí àìmọ́ gbogbo,
àti ilé fún ẹyẹ àìmọ́ gbogbo,
ilé fún ẹranko ìríra àti àìmọ́ gbogbo. 3Nítorí nípa ọtí wáìnì ìrunú àgbèrè rẹ̀ ni
gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú.
Àwọn ọba ayé sì ti bá a ṣe àgbèrè,
àti àwọn oníṣòwò ayé sì di ọlọ́rọ̀ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọ̀bìà rẹ̀.” 4Mo sì gbọ́ ohùn mìíràn láti ọ̀run wá, wí pé:
“ ‘Ẹ ti inú rẹ̀ jáde, ẹ̀yin ènìyàn mi,’
kí ẹ ma bá a ṣe alábápín nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,
kí ẹ ma bà á sì ṣe gbà nínú ìyọnu rẹ̀. 5Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ga títí dé ọ̀run,
Ọlọ́run sì ti rántí àìṣedéédéé rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.