Ìfihàn 18:10
Revelation 18:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n ó dúró ní òkèrè réré nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ́ oró rẹ̀, wọn ó máa wí pé: “ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà, Babeli ìlú alágbára nì! Nítorí ní wákàtí kan ni ìdájọ́ rẹ dé!’
Revelation 18:10 in English
Revelation 18:10 · Berean Standard Bible
In fear of her torment, they will stand at a distance and cry out: “Woe, woe to the great city, the mighty city of Babylon! For in a single hour your judgment has come.”
Context
8Nítorí náà, ní ọjọ́ kan ni ìyọnu rẹ̀ yóò dé,
ikú, àti ìbìnújẹ́, àti ìyàn;
a ó sì fi iná sun ún pátápátá:
nítorí pé alágbára ni Olúwa Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀. 9“Àti àwọn ọba ayé, tí ó ti ń bá a ṣe àgbèrè, tiwọn sì ń hùwà wọ̀bìà, yóò sì pohùnréré ẹkún lé e lórí, nígbà tí wọn bá wo èéfín ìjóná rẹ̀. 10Wọ́n ó dúró ní òkèrè réré nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ́ oró rẹ̀, wọn ó máa wí pé:
“ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà,
Babeli ìlú alágbára nì!
Nítorí ní wákàtí kan ni ìdájọ́ rẹ dé!’ 11“Àwọn oníṣòwò ayé sì ń sọkún, wọn sì ń ṣọ̀fọ̀ lórí rẹ̀, nítorí pé ẹnikẹ́ni kò rà ọjà wọn mọ́. 12Ọjà wúrà, àti ti fàdákà, àti ti òkúta iyebíye, àti ti perli, àti ti aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, àti tí elése àlùkò, àti ti ṣẹ́dà, àti ti òdòdó, àti ti gbogbo igi olóòórùn dídùn, àti ti olúkúlùkù ohun èlò tí a fi igi iyebíye ṣe, àti ti idẹ, àti ti irin, àti ti òkúta mabu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.