Native Bible

Revelation 17:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Níhìn-ín ni ìtumọ̀ tí o ní ọgbọ́n wà. Orí méje ni òkè ńlá méje ni, lórí èyí tí obìnrin náà jókòó.

Revelation 17:9 in English

Revelation 17:9 · Berean Standard Bible

This calls for a mind with wisdom. The seven heads are seven mountains on which the woman sits.

Context

7Angẹli sì wí fún mi pé, “Nítorí kí ni ẹnu ṣe yà ọ́? Èmi ó sọ ti ìjìnlẹ̀ obìnrin náà fún ọ, àti ti ẹranko tí ó gùn, ti ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá. 8Ẹranko tí ìwọ ri nì, o ti wà, kò sì ṣí mọ́, yóò sì ti inú ọ̀gbun gòkè wá, yóò sì lọ sínú ìparun rẹ. Àwọn olùgbé ayé ti a kọ orúkọ wọn sínú ìwé iye láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, nígbà tí wọn ń wò ẹranko tí o ti wà, tí kò sì ṣí mọ́, tí ó sì ń bọ̀ wá, ẹnu si ya wọn. 9“Níhìn-ín ni ìtumọ̀ tí o ní ọgbọ́n wà. Orí méje ni òkè ńlá méje ni, lórí èyí tí obìnrin náà jókòó. 10Ọba méje sì ní wọn: àwọn márùn-ún ṣubú, ọ̀kan ń bẹ, ọ̀kan ìyókù kò sì tí ì dé; nígbà tí ó bá sì dé, yóò dúró fún ìgbà kúkúrú. 11Ẹranko tí ó sì ti wà, tí kò sì ṣí, òun náà sì ni ẹ̀kẹjọ, ó sì ti inú àwọn méje náà wá, ó sì lọ sí ìparun.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.