Ìfihàn 17:11
Revelation 17:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹranko tí ó sì ti wà, tí kò sì ṣí, òun náà sì ni ẹ̀kẹjọ, ó sì ti inú àwọn méje náà wá, ó sì lọ sí ìparun.
Revelation 17:11 in English
Revelation 17:11 · Berean Standard Bible
The beast that was, and now is not, is an eighth king, who belongs to the other seven and is going into destruction.
Context
9“Níhìn-ín ni ìtumọ̀ tí o ní ọgbọ́n wà. Orí méje ni òkè ńlá méje ni, lórí èyí tí obìnrin náà jókòó. 10Ọba méje sì ní wọn: àwọn márùn-ún ṣubú, ọ̀kan ń bẹ, ọ̀kan ìyókù kò sì tí ì dé; nígbà tí ó bá sì dé, yóò dúró fún ìgbà kúkúrú. 11Ẹranko tí ó sì ti wà, tí kò sì ṣí, òun náà sì ni ẹ̀kẹjọ, ó sì ti inú àwọn méje náà wá, ó sì lọ sí ìparun. 12“Ìwo mẹ́wàá tí ìwọ sì rí ni ọba mẹ́wàá ni wọn, tí wọn kò ì ti gba ìjọba; ṣùgbọ́n wọn gba àṣẹ bí ọba pẹ̀lú ẹranko náà fún wákàtí kan. 13Àwọn wọ̀nyí ní inú kan, wọ́n yóò sì fi agbára àti ọlá wọn fún ẹranko náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.