Ìfihàn 17:10
Revelation 17:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọba méje sì ní wọn: àwọn márùn-ún ṣubú, ọ̀kan ń bẹ, ọ̀kan ìyókù kò sì tí ì dé; nígbà tí ó bá sì dé, yóò dúró fún ìgbà kúkúrú.
Revelation 17:10 in English
Revelation 17:10 · Berean Standard Bible
There are also seven kings. Five have fallen, one is, and the other has not yet come; but when he does come, he must remain for only a little while.
Context
8Ẹranko tí ìwọ ri nì, o ti wà, kò sì ṣí mọ́, yóò sì ti inú ọ̀gbun gòkè wá, yóò sì lọ sínú ìparun rẹ. Àwọn olùgbé ayé ti a kọ orúkọ wọn sínú ìwé iye láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, nígbà tí wọn ń wò ẹranko tí o ti wà, tí kò sì ṣí mọ́, tí ó sì ń bọ̀ wá, ẹnu si ya wọn. 9“Níhìn-ín ni ìtumọ̀ tí o ní ọgbọ́n wà. Orí méje ni òkè ńlá méje ni, lórí èyí tí obìnrin náà jókòó. 10Ọba méje sì ní wọn: àwọn márùn-ún ṣubú, ọ̀kan ń bẹ, ọ̀kan ìyókù kò sì tí ì dé; nígbà tí ó bá sì dé, yóò dúró fún ìgbà kúkúrú. 11Ẹranko tí ó sì ti wà, tí kò sì ṣí, òun náà sì ni ẹ̀kẹjọ, ó sì ti inú àwọn méje náà wá, ó sì lọ sí ìparun. 12“Ìwo mẹ́wàá tí ìwọ sì rí ni ọba mẹ́wàá ni wọn, tí wọn kò ì ti gba ìjọba; ṣùgbọ́n wọn gba àṣẹ bí ọba pẹ̀lú ẹranko náà fún wákàtí kan.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.