Ìfihàn 13:11
Revelation 13:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo sì rí ẹranko mìíràn gòkè láti inú ilẹ̀ wá; ó sì ní ìwo méjì bí ọ̀dọ́-àgùntàn, ó sì ń sọ̀rọ̀ bí dragoni.
Revelation 13:11 in English
Revelation 13:11 · Berean Standard Bible
Then I saw another beast rising out of the earth. This beast had two horns like a lamb, but spoke like a dragon.
Context
9Bí ẹnikẹ́ni bá létí kí o gbọ́. 10Ẹni tí a ti pinnu rẹ̀ fún ìgbèkùn,
ìgbèkùn ni yóò lọ;
ẹni tí a sì ti pinnu rẹ̀ fún idà,
ni a ó sì fi idà pa.
Níhìn-ín ni sùúrù àti ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn mímọ́ wà. 11Mo sì rí ẹranko mìíràn gòkè láti inú ilẹ̀ wá; ó sì ní ìwo méjì bí ọ̀dọ́-àgùntàn, ó sì ń sọ̀rọ̀ bí dragoni. 12Ó sì ń lo gbogbo agbára ẹranko èkínní níwájú rẹ̀, ó sì mú ilẹ̀ ayé àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ foríbalẹ̀ fún ẹranko èkínní tí a ti wo ọgbẹ́ àṣápa rẹ̀ sàn. 13Ó sì ń ṣe ohun ìyanu ńlá, àní tí ó fi ń mú iná sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá sì ilẹ̀ ayé níwájú àwọn ènìyàn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.