Native Bible

Revelation 13:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì ń lo gbogbo agbára ẹranko èkínní níwájú rẹ̀, ó sì mú ilẹ̀ ayé àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ foríbalẹ̀ fún ẹranko èkínní tí a ti wo ọgbẹ́ àṣápa rẹ̀ sàn.

Revelation 13:12 in English

Revelation 13:12 · Berean Standard Bible

And this beast exercised all the authority of the first beast and caused the earth and those who dwell in it to worship the first beast, whose mortal wound had been healed.

Context

10Ẹni tí a ti pinnu rẹ̀ fún ìgbèkùn, ìgbèkùn ni yóò lọ; ẹni tí a sì ti pinnu rẹ̀ fún idà, ni a ó sì fi idà pa. Níhìn-ín ni sùúrù àti ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn mímọ́ wà. 11Mo sì rí ẹranko mìíràn gòkè láti inú ilẹ̀ wá; ó sì ní ìwo méjì bí ọ̀dọ́-àgùntàn, ó sì ń sọ̀rọ̀ bí dragoni. 12Ó sì ń lo gbogbo agbára ẹranko èkínní níwájú rẹ̀, ó sì mú ilẹ̀ ayé àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ foríbalẹ̀ fún ẹranko èkínní tí a ti wo ọgbẹ́ àṣápa rẹ̀ sàn. 13Ó sì ń ṣe ohun ìyanu ńlá, àní tí ó fi ń mú iná sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá sì ilẹ̀ ayé níwájú àwọn ènìyàn. 14Ó sì ń tán àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé jẹ nípa àwọn ohun ìyanu tí a fi fún un láti ṣe níwájú ẹranko náà; ó wí fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé láti ya àwòrán fún ẹranko náà tí o tí gbá ọgbẹ́ idà, tí ó sì yè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.