Native Bible

Revelation 12:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí dragoni náà rí pé a lé òun lọ sí ilẹ̀ ayé, ó ṣe inúnibíni sì obìnrin tí ó bí ọmọkùnrin náà.

Revelation 12:13 in English

Revelation 12:13 · Berean Standard Bible

And when the dragon saw that he had been thrown to the earth, he pursued the woman who had given birth to the male child.

Context

11Wọ́n sì ti ṣẹ́gun rẹ̀ nítorí ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́-àgùntàn náà, àti nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀rí wọn, wọn kò sì fẹ́ràn ẹ̀mí wọn àní títí dé ikú. 12Nítorí náà ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, àti ẹ̀yin tí ń gbé inú wọn. Ègbé ni fún ayé àti Òkun; nítorí èṣù sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá ní ìbínú ńlá, nítorí ó mọ̀ pé ìgbà kúkúrú sá ni òun ní.” 13Nígbà tí dragoni náà rí pé a lé òun lọ sí ilẹ̀ ayé, ó ṣe inúnibíni sì obìnrin tí ó bí ọmọkùnrin náà. 14A sì fi apá ìyẹ́ méjì tí idì ńlá náà fún obìnrin náà, pé kí ó fò lọ sí aginjù, sí ipò rẹ̀, níbi tí a ó gbe bọ ọ fún àkókò kan àti fún àwọn àkókò, àti fún ìdajì àkókò kúrò lọ́dọ̀ ejò náà. 15Ejò náà sì tu omi jáde láti ẹnu rẹ̀ wá bí odò ńlá sẹ́yìn obìnrin náà, kí ó lè fi ìṣàn omi náà gbà á lọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.