Native Bible

Revelation 12:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ejò náà sì tu omi jáde láti ẹnu rẹ̀ wá bí odò ńlá sẹ́yìn obìnrin náà, kí ó lè fi ìṣàn omi náà gbà á lọ.

Revelation 12:15 in English

Revelation 12:15 · Berean Standard Bible

Then from the mouth of the serpent spewed water like a river to overtake the woman and sweep her away in the torrent.

Context

13Nígbà tí dragoni náà rí pé a lé òun lọ sí ilẹ̀ ayé, ó ṣe inúnibíni sì obìnrin tí ó bí ọmọkùnrin náà. 14A sì fi apá ìyẹ́ méjì tí idì ńlá náà fún obìnrin náà, pé kí ó fò lọ sí aginjù, sí ipò rẹ̀, níbi tí a ó gbe bọ ọ fún àkókò kan àti fún àwọn àkókò, àti fún ìdajì àkókò kúrò lọ́dọ̀ ejò náà. 15Ejò náà sì tu omi jáde láti ẹnu rẹ̀ wá bí odò ńlá sẹ́yìn obìnrin náà, kí ó lè fi ìṣàn omi náà gbà á lọ. 16Ilẹ̀ sì ran obìnrin náà lọ́wọ́, ilẹ̀ sì ya ẹnu rẹ̀, ó sì fi ìṣàn omi náà mú, tí dragoni náà tu jáde láti ẹnu rẹ̀ wá. 17Dragoni náà sì bínú gidigidi sí obìnrin náà, ó sì lọ bá àwọn irú-ọmọ rẹ̀ ìyókù jagun, tí wọ́n ń pa òfin Ọlọ́run mọ̀, tí wọn sì di ẹ̀rí Jesu mú, Ó sì dúró lórí iyanrìn Òkun.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.