Ìfihàn 11:17
Revelation 11:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
wí pé: “Àwa fi ọpẹ́ fún ọ, Olúwa Ọlọ́run, Olódùmarè, tí ń bẹ, tí ó sì ti wà, nítorí pé ìwọ ti gba agbára ńlá rẹ̀, ìwọ sì ti jẹ ọba.
Revelation 11:17 in English
Revelation 11:17 · Berean Standard Bible
saying: “We give thanks to You, O Lord God Almighty, the One who is and who was,* because You have taken Your great power and have begun to reign.
Context
15Angẹli keje sì fọn ìpè; a sì gbọ́ ohùn ńlá láti ọ̀run, wí pé,
“Ìjọba ayé di ti Olúwa wá, àti tí Kristi rẹ̀;
òun yóò sì jẹ ọba láé àti láéláé!” 16Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà tí wọn jókòó níwájú Ọlọ́run lórí ìtẹ́ wọn, dojúbolẹ̀, wọn sì sin Ọlọ́run, 17wí pé:
“Àwa fi ọpẹ́ fún ọ, Olúwa Ọlọ́run, Olódùmarè,
tí ń bẹ, tí ó sì ti wà,
nítorí pé ìwọ ti gba agbára ńlá rẹ̀,
ìwọ sì ti jẹ ọba. 18Inú bí àwọn orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú rẹ̀ ti dé,
àti àkókò láti dá àwọn òkú lẹ́jọ́,
àti láti fi èrè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì,
àti àwọn ènìyàn mímọ́, àti àwọn tí o bẹ̀rù orúkọ rẹ̀,
àti ẹni kékeré àti ẹni ńlá;
àti láti run àwọn tí ń pa ayé run.” 19A sì ṣí tẹmpili Ọlọ́run sílẹ̀ ní ọ̀run, a sì ri àpótí májẹ̀mú nínú tẹmpili rẹ̀. Mọ̀nàmọ́ná sì kọ, a sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, ilẹ̀ sì mi, yìnyín ńlá sì bọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.