Ìfihàn 11:15
Revelation 11:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Angẹli keje sì fọn ìpè; a sì gbọ́ ohùn ńlá láti ọ̀run, wí pé, “Ìjọba ayé di ti Olúwa wá, àti tí Kristi rẹ̀; òun yóò sì jẹ ọba láé àti láéláé!”
Revelation 11:15 in English
Revelation 11:15 · Berean Standard Bible
Then the seventh angel sounded his trumpet, and loud voices called out in heaven: “The kingdom of the world has become the kingdom of our Lord and of His Christ, and He will reign forever and ever.”
Context
13Ní wákàtí náà omìmì-ilẹ̀ ńlá kan sì mì, ìdámẹ́wàá ìlú náà sì wó, àti nínú omìmì-ilẹ̀ náà ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) ènìyàn ní a pa; ẹ̀rù sì ba àwọn ìyókù, wọn sì fi ògo fún Ọlọ́run ọ̀run. 14Ègbé kejì kọjá; sì kíyèsi i, ègbé kẹta sì ń bọ̀ wá kánkán. 15Angẹli keje sì fọn ìpè; a sì gbọ́ ohùn ńlá láti ọ̀run, wí pé,
“Ìjọba ayé di ti Olúwa wá, àti tí Kristi rẹ̀;
òun yóò sì jẹ ọba láé àti láéláé!” 16Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà tí wọn jókòó níwájú Ọlọ́run lórí ìtẹ́ wọn, dojúbolẹ̀, wọn sì sin Ọlọ́run, 17wí pé:
“Àwa fi ọpẹ́ fún ọ, Olúwa Ọlọ́run, Olódùmarè,
tí ń bẹ, tí ó sì ti wà,
nítorí pé ìwọ ti gba agbára ńlá rẹ̀,
ìwọ sì ti jẹ ọba.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.