Saamu 90:12
Psalms 90:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kọ́ wa bí a ti ń kaye ọjọ́ wa dáradára, kí àwa ba à lè fi ọkàn wa sípa ọgbọ́n.
Psalms 90:12 in English
Psalms 90:12 · Berean Standard Bible
So teach us to number our days, that we may present a heart of wisdom.
Context
10Àádọ́rin ọdún ni iye ọjọ́ ọdún wá,
bi ó sì ṣe pé nípa agbára
tí wọn bá tó ọgọ́rin ọdún,
agbára nínú làálàá pẹ̀lú ìbànújẹ́ ni,
nítorí pé a kò ní pẹ́ gé e kúrò,
àwa a sì fò lọ. 11Ta ni ó mọ agbára ìbínú rẹ?
Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rù rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú rẹ. 12Kọ́ wa bí a ti ń kaye ọjọ́ wa dáradára,
kí àwa ba à lè fi ọkàn wa sípa ọgbọ́n. 13Yípadà, Olúwa! Yóò ti pẹ́ tó?
Ṣàánú fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ. 14Tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀ nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ,
kí àwa kí ó lè kọrin fún ayọ̀
kí inú wa sì dùn ní gbogbo ọjọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.