Saamu 88:7
Psalms 88:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìbínú rẹ ṣubú lé mi gidigidi; ìwọ ti fi àwọn ìjì rẹ borí mi.
Psalms 88:7 in English
Psalms 88:7 · Berean Standard Bible
Your wrath weighs heavily upon me; all Your waves have submerged me. Selah
Context
5A yà mí sọ́tọ̀ pẹ̀lú àwọn òkú
bí ẹni tí a pa tí ó dùbúlẹ̀ ní ipò ikú,
ẹni tí ìwọ kò rántí mọ́,
ẹni tí a gé kúrò lára àwọn tí ìwọ ń tọ́jú. 6Ìwọ tí ó fi mí sí kòtò jíjìn,
ní ibi ọ̀gbun tó ṣókùnkùn. 7Ìbínú rẹ ṣubú lé mi gidigidi;
ìwọ ti fi àwọn ìjì rẹ borí mi. 8Ìwọ tí gba ọ̀rẹ́ mi tí ó súnmọ́ mi kúrò lọ́wọ́ mi
ìwọ sì sọ mi di ìríra sí wọn.
A há mi mọ́, èmi kò sì le è jáde; 9ojú mi káàánú nítorí ìpọ́njú.
Mo kígbe pè ọ́, Olúwa, ní gbogbo ọjọ́;
mo na ọwọ́ mi jáde sí ọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.