Native Bible

Psalms 86:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣàánú fún mi, Olúwa, nítorí èmi ń pè ọ́ ní gbogbo ọjọ́.

Psalms 86:3 in English

Psalms 86:3 · Berean Standard Bible

Be merciful to me, O Lord, for I call to You all day long.

Context

1Gbọ́, Olúwa, kí o sì dá mi lóhùn, nítorí mo jẹ́ tálákà àti aláìní. 2Dáàbò bò ayé mi, nítorí a ti yà mí sọ́tọ̀ fún ọ: ìwọ ni Ọlọ́run mi, gbà ìránṣẹ́ rẹ là tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ. 3Ṣàánú fún mi, Olúwa, nítorí èmi ń pè ọ́ ní gbogbo ọjọ́. 4Mú ayọ̀ wà fún ìránṣẹ́ rẹ, nítorí ìwọ, Olúwa, ni mo gbé ọkàn mí sókè sí. 5Ìwọ ń dáríjì, ìwọ sì dára, Olúwa, ìwọ sì ṣàánú fún gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.