Saamu 81:9
Psalms 81:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ̀yin kì yóò ní Ọlọ́run ilẹ̀ mìíràn láàrín yín; ẹ̀yin kì yóò foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run àjèjì.
Psalms 81:9 in English
Psalms 81:9 · Berean Standard Bible
There must be no strange god among you, nor shall you bow to a foreign god.
Context
7Nínú ìnilára ni ẹ pè mo sì gbà yín là,
mo dá a yín lóhùn nínú ìkọ̀kọ̀ àrá,
mo dán an yín wò ní odò Meriba. Sela. 8“Gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi ó sì kìlọ̀ fún un yín,
bí ìwọ bá fetí sí mi, ìwọ Israẹli. 9Ẹ̀yin kì yóò ní Ọlọ́run ilẹ̀ mìíràn láàrín yín;
ẹ̀yin kì yóò foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run àjèjì. 10Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
ẹni tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti.
Ẹ la ẹnu yín gbòòrò, èmi yóò sì kún un. 11“Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kì yóò gbọ́ tèmi;
Israẹli kò ní tẹríba fún mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.