Native Bible

Psalms 81:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nínú ìnilára ni ẹ pè mo sì gbà yín là, mo dá a yín lóhùn nínú ìkọ̀kọ̀ àrá, mo dán an yín wò ní odò Meriba. Sela.

Psalms 81:7 in English

Psalms 81:7 · Berean Standard Bible

You called out in distress, and I rescued you; I answered you from the cloud of thunder; I tested you at the waters of Meribah.* Selah

Context

5Ó fi múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún Josẹfu nígbà tí ó la ilẹ̀ Ejibiti já. Níbi tí a ti gbọ́ èdè tí kò yé wa. 6Ó wí pé, “Mo gbé àjàgà kúrò ní èjìká yín, a tú ọwọ́ wọn sílẹ̀ kúrò nínú apẹ̀rẹ̀. 7Nínú ìnilára ni ẹ pè mo sì gbà yín là, mo dá a yín lóhùn nínú ìkọ̀kọ̀ àrá, mo dán an yín wò ní odò Meriba. Sela. 8“Gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi ó sì kìlọ̀ fún un yín, bí ìwọ bá fetí sí mi, ìwọ Israẹli. 9Ẹ̀yin kì yóò ní Ọlọ́run ilẹ̀ mìíràn láàrín yín; ẹ̀yin kì yóò foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run àjèjì.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.