Saamu 78:4
Psalms 78:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwa kì yóò pa wọ́n mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ, ní fífi ìyìn Olúwa, àti ipa rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu tó ti ṣe hàn fún ìran tí ń bọ̀.
Psalms 78:4 in English
Psalms 78:4 · Berean Standard Bible
We will not hide them from their children, but will declare to the next generation the praises of the LORD and His might, and the wonders He has performed.
Context
2Èmi ó la ẹnu mi ní òwe,
èmi o sọ ohun ìkọ̀kọ̀, ohun ti ọjọ́ pípẹ́; 3ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀,
ohun tí àwọn baba wa ti sọ fún wa. 4Àwa kì yóò pa wọ́n mọ́
kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ,
ní fífi ìyìn Olúwa, àti ipa rẹ̀
àti iṣẹ́ ìyanu tó ti ṣe hàn
fún ìran tí ń bọ̀. 5Ó gbé ẹ̀rí kalẹ̀ ní Jakọbu
o sì fìdí àṣẹ múlẹ̀ ní Israẹli,
èyí tí ó pàṣẹ fún àwọn baba ńlá wa
láti kọ́ àwọn ọmọ wọn, 6nítorí náà, àwọn ìran tí ń bọ̀ yóò mọ̀ wọ́n
bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí
tí yóò dìde tí wọn yóò sọ fún àwọn ọmọ wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.