Native Bible

Psalms 73:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọn ń ṣẹ̀sín, wọn sì ń sọ̀rọ̀-òdì ní ti ìnilára, wọ́n ń sọ̀rọ̀ láti ibi gíga.

Psalms 73:8 in English

Psalms 73:8 · Berean Standard Bible

They mock and speak with malice; with arrogance they threaten oppression.

Context

6Ìgbéraga ni ọ̀ṣọ́ ọrùn wọn; ìwà ipá bò wọ́n mọ́lẹ̀ bí aṣọ. 7Láti inú ọkàn àrékérekè ni àìṣòdodo ti wá; ẹ̀rí ọkàn búburú wọn kò ní òdínwọ̀n. 8Wọn ń ṣẹ̀sín, wọn sì ń sọ̀rọ̀-òdì ní ti ìnilára, wọ́n ń sọ̀rọ̀ láti ibi gíga. 9Wọ́n ń gbé ẹ̀mí wọn lé ọ̀run ahọ́n wọn gba ipò ayé. 10Nítorí náà àwọn ènìyàn wọn yípadà sí wọn wọ́n sì mu omi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.