Native Bible

Psalms 71:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ ti mú mi rí ìdààmú, tí ó pọ̀ tí ó sì korò, ìwọ yóò tún sọ ayé mi jí ìwọ yóò sì tún mú mi sọ sókè láti ọ̀gbun ilẹ̀ wá. Ìwọ yóò sọ ọlá mi di púpọ̀.

Psalms 71:20 in English

Psalms 71:20 · Berean Standard Bible

Though You have shown me many troubles and misfortunes, You will revive me once again. Even from the depths of the earth You will bring me back up.

Context

18Pẹ̀lúpẹ̀lú, nígbà tí èmi di arúgbó tán tí mo sì hewú, má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, Ọlọ́run mi, títí èmi ó fi ipá rẹ han ìran tí ń bọ̀, àti agbára rẹ fún gbogbo àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn. 19Ọlọ́run, òdodo rẹ dé ọ̀run, ìwọ tí o ti ṣe ohun ńlá. Ta ni ó dàbí rẹ, Ọlọ́run? 20Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ ti mú mi rí ìdààmú, tí ó pọ̀ tí ó sì korò, ìwọ yóò tún sọ ayé mi jí ìwọ yóò sì tún mú mi sọ sókè láti ọ̀gbun ilẹ̀ wá. Ìwọ yóò sọ ọlá mi di púpọ̀. 21Ìwọ yóò fi kún ọwọ́ mi ìwọ yóò tù mí nínú ní ha gbogbo. 22Èmi yóò fi dùùrù mi yìn fún òtítọ́ rẹ, Ọlọ́run mi; èmi ó kọrin ìyìn sí ọ pẹ̀lú dùùrù ìwọ ẹni mímọ́ Israẹli.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.