Native Bible

Psalms 71:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Pẹ̀lúpẹ̀lú, nígbà tí èmi di arúgbó tán tí mo sì hewú, má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, Ọlọ́run mi, títí èmi ó fi ipá rẹ han ìran tí ń bọ̀, àti agbára rẹ fún gbogbo àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn.

Psalms 71:18 in English

Psalms 71:18 · Berean Standard Bible

Even when I am old and gray, do not forsake me, O God, until I proclaim Your power to the next generation, Your might to all who are to come.

Context

16Èmi ó wá láti wá kéde agbára, Olúwa Olódùmarè; èmi ó kéde òdodo rẹ̀ nìkan. 17Láti ìgbà èwe, Ọlọ́run ni ìwọ ti kọ́ mi títí di òní ni mo ń sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ. 18Pẹ̀lúpẹ̀lú, nígbà tí èmi di arúgbó tán tí mo sì hewú, má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, Ọlọ́run mi, títí èmi ó fi ipá rẹ han ìran tí ń bọ̀, àti agbára rẹ fún gbogbo àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn. 19Ọlọ́run, òdodo rẹ dé ọ̀run, ìwọ tí o ti ṣe ohun ńlá. Ta ni ó dàbí rẹ, Ọlọ́run? 20Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ ti mú mi rí ìdààmú, tí ó pọ̀ tí ó sì korò, ìwọ yóò tún sọ ayé mi jí ìwọ yóò sì tún mú mi sọ sókè láti ọ̀gbun ilẹ̀ wá. Ìwọ yóò sọ ọlá mi di púpọ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.