Saamu 69:17
Psalms 69:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ: yára dá mi lóhùn, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú.
Psalms 69:17 in English
Psalms 69:17 · Berean Standard Bible
Hide not Your face from Your servant, for I am in distress. Answer me quickly!
Context
15Má ṣe jẹ́ kí ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀
bẹ́ẹ̀ ni má ṣe jẹ́ kí ọ̀gbìn gbé mi mì
kí o má sì ṣe jẹ́ kí ihò pa ẹnu rẹ̀ dé mọ́ mi. 16Dá mí lóhùn, Olúwa, nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ;
nínú ọ̀pọ̀ àánú rẹ yípadà sí mi. 17Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ:
yára dá mi lóhùn, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú. 18Súnmọ́ tòsí kí o sì gbà mí là;
rà mí padà nítorí àwọn ọ̀tá mi. 19Ìwọ ti mọ ẹ̀gàn mi, ìtìjú mi àti àìlọ́lá;
gbogbo àwọn ọ̀tá mi wà níwájú rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.