Native Bible

Psalms 69:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbà mí kúrò nínú ẹrẹ̀, má ṣe jẹ́ kí n rì; gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi, kúrò nínú ibú omi.

Psalms 69:14 in English

Psalms 69:14 · Berean Standard Bible

Rescue me from the mire and do not let me sink; deliver me from my foes and out of the deep waters.

Context

12Àwọn tí ó jókòó ní ẹnu ibodè ń bú mi, mo sì di orin àwọn ọ̀mùtí. 13Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni ìwọ ni èmi ń gbàdúrà mi sí Olúwa, ní ìgbà ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run, nínú ìfẹ́ títóbi rẹ, dá mi lóhùn pẹ̀lú ìgbàlà rẹ tí ó dájú. 14Gbà mí kúrò nínú ẹrẹ̀, má ṣe jẹ́ kí n rì; gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi, kúrò nínú ibú omi. 15Má ṣe jẹ́ kí ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni má ṣe jẹ́ kí ọ̀gbìn gbé mi mì kí o má sì ṣe jẹ́ kí ihò pa ẹnu rẹ̀ dé mọ́ mi. 16Dá mí lóhùn, Olúwa, nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ; nínú ọ̀pọ̀ àánú rẹ yípadà sí mi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.