Saamu 68:15
Psalms 68:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Òkè Baṣani jẹ́ òkè Ọlọ́run; òkè tí ó ní orí púpọ̀ ni òkè Baṣani.
Psalms 68:15 in English
Psalms 68:15 · Berean Standard Bible
A mountain of God is Mount Bashan; a mountain of many peaks is Mount Bashan.
Context
13Nígbà tí ẹ̀yin dùbúlẹ̀ láàrín agbo ẹran,
nígbà náà ni ẹ̀yin ó dàbí ìyẹ́ àdàbà ti a bò ní fàdákà,
àti ìyẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú wúrà pupa.” 14Nígbà tí Olódùmarè fọ́n àwọn ọba ká ní ilẹ̀ náà,
ó dàbí òjò dídi ní Salmoni. 15Òkè Baṣani jẹ́ òkè Ọlọ́run;
òkè tí ó ní orí púpọ̀ ni òkè Baṣani. 16Kí ló dé tí ẹ̀yin fi ń ṣe ìlara,
ẹ̀yin òkè wúwo, òkè tí Ọlọ́run ti fẹ́ láti jẹ ọba
níbi tí Olúwa fúnra rẹ̀ yóò máa gbé títí láé? 17Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ni kẹ̀kẹ́ ogun Ọlọ́run
ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún;
Olúwa ń bẹ láàrín wọn, ní Sinai ni ibi mímọ́ rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.