Saamu 64:4
Psalms 64:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n tafà ní ìkọ̀kọ̀ sí àwọn aláìlẹ́ṣẹ̀: wọ́n tafà si lójijì, wọn kò sì bẹ̀rù.
Psalms 64:4 in English
Psalms 64:4 · Berean Standard Bible
ambushing the innocent in seclusion, shooting suddenly, without fear.
Context
2Pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ àwọn ènìyàn búburú
kúrò nínú ọ̀pọ̀ igbe lọ́wọ́ ìrúkèrúdò oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. 3Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn bí idà,
wọ́n sì fa ọrun wọn le láti tafà wọn, àní ọ̀rọ̀ kíkorò. 4Wọ́n tafà ní ìkọ̀kọ̀ sí àwọn aláìlẹ́ṣẹ̀:
wọ́n tafà si lójijì, wọn kò sì bẹ̀rù. 5Wọ́n, gba ara wọn níyànjú nínú èrò búburú,
wọ́n sọ̀rọ̀ lórí dídẹkùn sílẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀
wọ́n wí pé, “Ta ni yóò rí wa?” 6Wọ́n gbìmọ̀ àìṣòdodo, wọ́n wí pé,
“A wa ti parí èrò tí a gbà tán!”
Lóòótọ́ àyà àti ọkàn ènìyàn kún fún àrékérekè.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.