Saamu 63
Psalms 63 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
1Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run mi,
nígbà gbogbo ni mo ń ṣàfẹ́rí rẹ,
òǹgbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi,
ara mi fà sí ọ,
ní ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tí ń ṣàárẹ̀
níbi tí kò sí omi. 2Èmi ti rí ọ ní ibi mímọ́,
mo rí agbára àti ògo rẹ. 3Nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ayé lọ,
ètè mi yóò fògo fún ọ. 4Èmi ó yìn ọ́ níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè,
èmi ó gbé ọwọ́ sókè, èmi ó sì pe orúkọ rẹ. 5A ó tẹ́ ọkàn mi lọ́rùn bí ọlọ́ràá oúnjẹ;
pẹ̀lú ètè ìyìn, ẹnu mi yóò yìn ọ́. 6Nígbà tí mo rántí rẹ lórí ibùsùn mi;
èmi ń ronú rẹ títí ìṣọ́ òru. 7Nítorí ìwọ ni ìrànlọ́wọ́ mi,
mo kọrin níbi òjìji ìyẹ́ apá rẹ. 8Ọkàn mí fà sí ọ:
ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbé mi ró. 9Àwọn tí ó ń wá ọkàn mí ni a ó parun;
wọn ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé. 10Wọn ó ti ọwọ́ idà ṣubú
wọn ó sì di jíjẹ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀. 11Ṣùgbọ́n ọba yóò yọ̀ nínú Ọlọ́run
ẹni tí ó fi orúkọ Ọlọ́run búra yóò ṣògo
ṣùgbọ́n ẹnu àwọn òpùrọ́ la ó pamọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.