Saamu 61
Psalms 61 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
1Gbọ́ ẹkún mi, Ọlọ́run;
tẹ́tí sí àdúrà mi. 2Láti òpin ayé wá ni èmi yóò pè ọ́,
mo pè nígbà àyà mi ń ṣàárẹ̀;
mú mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ. 3Nítorí ìwọ ti jẹ́ ibi ààbò mi,
ilé ìṣọ́ agbára àwọn ọ̀tá. 4Mo ń lépa láti máa gbé nínú àgọ́ rẹ títí láé
kí n sì rí ààbò níbi ìyẹ́ apá rẹ. 5Nítorí ìwọ ti gbọ́ àwọn ẹ̀jẹ́ mi, Ọlọ́run;
Ìwọ ti fún mi ní ogún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ. 6Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn,
ọdún rẹ̀ fún ìrandíran. 7Kí ó máa jẹ ọba níwájú Ọlọ́run títí láé;
pèsè àánú àti òtítọ́ rẹ tí yóò máa ṣe ìtọ́jú rẹ. 8Nígbà náà ni èmi ó máa kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ títí láé
kí n san ẹ̀jẹ́ mi ní ojoojúmọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.